Àwọn Akọni Super Falcons Ti Gba Tikẹẹti WAFCON 2026
Àwọn Super Falcons ti Nàìjíríà ti yege lati kopa ninu Ife Awọn Obirin Ilẹ Adulawo (WAFCON) ti ọdún 2026, lẹ́yìn ti wọn gba ayo 1-1 pelu awọn agbaboolu Amazons ti Orílẹ̀-èdè Benin ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Iṣẹ́gun ni Moshood Abiola Stadium. Àbájáde yìí fi han wipe wọn bori àwọn Amazons pelu àpapọ̀ àmì 3-1.
Ìyege Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ láti eré àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣẹ́gun pẹ̀lú àwọn àmì 2-0 ní ìlú Lomé, Togo, ní ọjọ́ Ẹtì tó kọjá. Ní ìkópa padà yìí, Ashleigh Plumptre ló kọkọ fi òrí-kíkan gba bọọlu sinu awọn ní ìṣẹ́jú kejìlá fún Super Falcons.
Sùgbọ́n, awọn àlejò náà kò gbà láti juwọ́ sílẹ̀, wọ́n wá rí àmì tí ó mú wọn bá Nàìjíríà dọ́gba ní ìṣẹ́jú kọkànlélọ́gọ́ta nípasẹ̀ Yasminath Djibril. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wà ní àmì kan náà lóru ọjọ́ náà, ìrírí àti àǹfààní àmì méjì (2) tí Nàìjíríà ní láti eré àkọ́kọ́ jẹ́ kí wọ́n lè fòpin sí ìdíje náà kí wọ́n sì fìdí ìrìn-àjò wọn múlẹ̀ fún kikopa ninu WAFCON tí yóò wáyé ní Mòrókò.
Ìyege yìí ti mú kí Nàìjíríà ni àkọsílẹ̀ rẹ̀ tí kò láfiwé, gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo tí ó ti kópa ní gbogbo WAFCON láti ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ titi di isinsinyi.
Àwọn Super Falcons yóò bere si mura fun idije ti yoo waye ní Mòrókò, tí a ṣètò rẹ̀ láti March 17 sí April 3, 2026, níbi tí wọ́n ti máa wéwèé láti bori kí wọ́n sì fìdí ìyege wọn múlẹ̀ fún kikopa ninu Ifẹ Agbáyé FIFA Àwọn Obinrin (FIFA Women's World Cup) ti ọdún 2027.