EFCC Fi Ilé, Mọ́tò, Àti Owó Tí Wọ́n Gbà Lọ́wọ́ Bàbáláwo Onijìbìtì Fun Olohun
Àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìjìbìtì lórí owó, iṣúná àti Ìwà Ọ̀daràn (EFCC), ti fi àwọn dúkìà kan tí wọ́n gbà padà lọ́wọ́ bàbáláwo onijìbìtì, Fatai Olalere Alli, lé olohun lọwọ, iyẹn Daniel Babatunde Attiogbe, ní ọjọ́rú ọ̀sẹ̀ yìí.
Àwọn dúkìà tí wọ́n fi lé Ọ̀gbẹ́ni Attiogbe lọ́wọ́ ni ilé mẹ́ta, mọ́tò olówó-iyebíye méjì, àti iye owó ₦1.1 million.
Adele Oludari EFCC ni agbegbe Ibadan Hauwa Garba Ringim ti iṣe asoju fun, Alága Ìgbìmọ̀ EFCC, Ola Olukoyede, sọ pé bí àwọn ṣe ń da àwọn dúkìà náà padà fún ẹni tí oni yìí jẹ́ àbájade-òfin-ilé-ẹjọ́. Ó tẹnu mọ́ ọn pé, àjọ náà ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ òfin.
Ile ẹjo rí pe Ọ̀gbẹ́ni Alli jẹ̀bi fifi ẹ̀tàn gba owó tí ó lé ní ₦200 million lọ́wọ́ Ọ̀gbẹ́ni Attiogbe. Alli tan Attiogbe jẹ pé òun fẹ́ ṣe "ìwẹnumọ́ ẹ̀mí" fún kí ó má baà kú.
Adájọ́ Uche Agomoh ti ilé ẹjọ́ Ijọba Àpapọ̀ ní ìlú Ìbàdàn ni ó pa àṣẹ fún idapada àwọn dúkìà náà lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ti da Alli lẹbi. Wọ́n dá Alli lẹ́bi ní ọdún 2024, wọ́n sì jù ú sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta.
Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Attiogbe ń gba àwọn ìwé-ẹ̀rí-olóhun àwọn dúkìà náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ EFCC fún ilakaka alaseyọri wọn. Ó sọ pé òun ti fẹ́ rẹ́wẹ̀sì nínú ọ̀rọ̀ náà ṣùgbọ́n EFCC ló tún jí ìrètí òun dìde.
