Ijọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà Fagile Físà Ọ̀mọ̀wé Wọlé Ṣóyínká
Ọ̀mọ̀wé Wọlé Ṣóyínká, ti ṣí i payá pé ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti fagile fíísà fun irinajo àtìgbà-dégbà (non-immigrant visa) tó jẹ́ tirẹ̀, èyí tí ó fi mọ́ ọn ní dandan láti rìnrìn-àjò lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Òǹkọ̀wé eré-oníṣe àti ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọ-èèyàn yìí sọ̀rọ̀ yìí lásìkò ìpàdé pẹ̀lú àwọn oníròyìn tí ó wáyé ní ọjọ́ Isẹgun, Ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, Oṣù Kẹwàá, Ọdún 2025, ní Kongi’s Harvest Gallery ní Ìpínlẹ̀ Èkó.
Ṣóyínká sọ pé ìwé àṣẹ ifagile fíísà náà dé bá òun ní ọjọ́ Kẹtalélógún Oṣù Kẹwàá, Ọdún 2025, láti ọ̀dọ̀ Iléeṣẹ́ Aṣojú Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà (U.S. Consulate General) ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ìwé náà fi ye e pé fíísà rẹ̀ tí wọ́n pè ní B1/B2 (èyí tí wọ́n máa ń fún ni fún ìrìn-àjò iṣẹ́-ìṣòwò tàbí irinajo fun faaji), ni ẹ̀ka-iṣẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àjèjì ti da duro, nítorí àwọn ohun titun tí ó fara hàn lẹ́hìn tí wọ́n fún un ní fíísà náà.
Ọ̀mọ̀wé Soyinka fi ìyàlẹ́nu rẹ̀ hàn, ó ní òun kò mọ̀ nípa òfin tàbí ìdí pàtó kankan fún ìgbésẹ̀ yìí. Ṣóyínká sọ pé: “Mo ṣì ń wòye ìtàn ìgbésí ayé mi tẹ́lẹ̀… N kò ní ìwé ẹ̀bi tẹ́lẹ̀ rí, tàbí ìwà-ọ̀daràn kékeré tàbí ńlá kankan tí yóò yẹ fún ifagile yìí,” ó sì tẹ̀ síwájú pé, “Ǹjẹ́ mo ti hùwà ibi sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà rí? Ǹjẹ́ mo ní ìtàn búburú kan níbẹ̀? Ǹjẹ́ wọ́n ti dá mi lẹ́bi rí? Ǹjẹ́ mo ti lọ lòdì sí òfin níbi kankan?”
Pẹ̀lú bí wọ́n ti kọ̀ ọ́, Omowe Ṣóyínká tẹnu mọ́ ọn pé kò gbẹ̀sàn kankan sí àwọn ará Amẹ́ríkà tàbí orílẹ̀-èdè náà. Ó fi kún un pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ rí mi, ó mọ ibi tí yóò ti bá mi,” ó ṣèlérí pé òun yóò máa gba àwọn ará Amẹ́ríkà lálejò ní Nàìjíríà, òun yóò sì máa sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìdájọ́ òdodo káríayé.
Iléeṣẹ́ Aṣojú Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti bèèrè pé kí Omowe Ṣóyínká gbé ìwé-ìrìnnà (passport) rẹ̀ wá fún ìfagilé fíísà náà ni ile isẹ wọn ní Ìpínlẹ̀ Èkó, ṣùgbọ́n kò sí àlàyé gbangba kankan tí wọ́n tíì ṣe nípa ìdí tí wọ́n fi fagile fiisa. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé lẹ́hìn tí Ṣóyínká ti sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ètò ìdarí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kan ní àtẹ̀yìnwá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò sọ tààràtà pé èyí ló fà á.
