Ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Donald Trump, ti sọ̀rọ̀ líle lórí oun to nlọ l'orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó halẹ̀ láti fòpin sí gbogbo ìrànwọ́ tí Amẹ́ríkà ń fún Nàìjíríà, ó tilẹ̀ tún sọ pé ó ṣeé ṣe kí awọn ologun Amẹ́ríkà wọlé sí orílẹ̀-èdè náà bí ìjọba Nàìjíríà kò bá gbógun ti pípa tí wọ́n ń pa àwọn Kristẹni láìfọ̀tápè.
Àwọn ọ̀rọ̀ líle wọ̀nyí, tí ó tẹ̀ jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára ní òpin ọ̀sẹ̀, tẹ̀ lé ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti tún pe Nàìjíríà ní “Orílẹ̀-Èdè Tí Ó Yẹ Kí A Fí Ojú Si Dada” (Country of Particular Concern [CPC]) orukọ ti ijọba Amẹ́ríkà fi ma n saami fun àwọn orílẹ̀-èdè ti ko fàyè gba ominira ẹ̀sìn. Trump sọ pé "Ìsìn Kristẹni dojú kọ ìsòrò pupọ ni Nàìjíríà," ó sì fi kún un pé òun ti pàṣẹ fún Ilé-iṣẹ́ Ọ̀darí Àwọn Ológun (Pentagon) láti múra sílẹ̀ fún ìgbésẹ̀ tó kan. Pípè tí wọ́n pe Nàìjíríà ní CPC yìí mú kí ó ṣeé ṣe fún Amẹ́ríkà láti ṣiṣẹ tako orílẹ̀-èdè náà.
Ìjọba Nàìjíríà, lábẹ́ Ààrẹ Bola Tinubu, tètè kọ ọ̀rọ̀ Ààrẹ Amẹ́ríkà náà, wọ́n sì sọ pé bí ó ṣe fi Nàìjíríà hàn gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀-èdè tí kò fàyè gba ẹ̀sìn "kò bá oun to nṣẹlẹ ni orílẹ̀-èdè wa mu." Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Nàìjíríà tẹnu mọ́ ọ pé ìwà ipá náà, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ oríṣiríṣi àwọn ẹgbẹ́ amúnisìn bíi Boko Haram, ISWAP, àti àwọn ọlọ́sà oníhàmọ́ra, ń kan gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè láìka ẹ̀sìn sí.
Mínísítà fún Ọ̀rọ̀ Ibasepọ Pẹlu Awọn Ilu Ati Ajọ Okeere, Yusuf Tuggar, tẹnu mọ́ ọ pé iwe ofin tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi ẹsẹ òmìnira ẹ̀sìn múlẹ, eyi simu "kò mọ ṣeé ṣe" fun ìjọba latì gbógun ti ẹsin kankan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbà pé ìrànwọ́ Amẹ́ríkà láti dojú kọ àwọn ẹgbẹ́ amúnisìn wúlò, wọ́n tẹnu mọ́ dandan pé ó yẹ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ Nàìjíríà láti máa dá duro gẹgẹ bi orílẹ̀-èdè.
Ohun pàtàkì tí o fa awuyewuye ni bí wọ́n ṣe ń túmọ̀ wàhálà ààbò tí ó díjú ní Nàìjíríà. Àwọn tí ó fẹ́ kí wọ́n pe orílẹ̀-èdè náà ní CPC, títí kan àwọn aṣòfin Amẹ́ríkà kan, jiyàn pé ìwádìí fi hàn pé àwọn Kristẹni ni wọ́n ń fojú sùn gan-an, pàápàá ní àgbègbè Àárín Gbùngbùn, láti ọwọ́ àwọn ẹgbẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìsìláàmù, àwọn darandaran àti àwọn ológun ẹ̀yà. Wọ́n tọ́ka sí pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni ni wọ́n sọ pé wọ́n ń pa lọ́dọọdún.
Lọ́nà mìíràn, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Nàìjíríà àti àwọn ẹgbẹ́ ètọ́ ọmọ ènìyàn àgbáyé bíi Amnesty International jiyàn pé ìwà ipá náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó bani nínú jẹ́, kò lè yẹ́ kí wọ́n sọpè Kristẹni nikan lo tábá. Wọ́n sọ pé àwọn ẹgbẹ́ apaniyàn àti àwọn ọlọ́sà ń ṣiṣẹ́ láìka ẹni kankan sí, wọ́n ń pa àwọn Mùsùlùmí àti àwọn Kristẹni bákan náà, nígbà púpọ̀ nínú ìforígbárí lórí ilẹ̀, ókó ati àlúmọni. Síwájú sí i, ìwà ipá tí wọ́n ṣe láti dojú kọ àwọn Kristẹni nítorí ẹ̀sìn jẹ́ díẹ̀ lára gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ń kọlu àwọn ará ìlú.
