Gómìnà Zulum Fidi Rẹ Mulẹ Pe Ọjà Jilli ti Di Tìtì Láti Ọdún Máàrún Sẹ́yìn Kí Ìkọlù Ọkọ̀ Òfurufú Tó Wáyé

Tosin Adegoke
0

Àwọn ọmọ ogun ojú òfurufú ti ilẹ̀ Nàìjíríà (NAF) ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú àwọn arálú nínú ìkọlù kan tó wáyé ní ọjà Jilli, tó wà láàárín ààlà ìpínlẹ̀ Borno àti Yobe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ológun sọ pé ibùdó àwọn agbésùnmọ̀mí ni wọ́n kọ lù, ìròyìn látọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú fihàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ẹ̀mí wọn bọ́ sí i nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà níbi ọjà tí ìjọba ti ní kò gbọ́dọ̀ ṣí mọ́.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, Babagana Zulum, sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ọjọ́ Ajé, ó sì tẹnumọ́ ọn pé ọjà Jilli àti Gazabure ti di títì láti ọdún 2021. Gómìnà ṣàlàyé pé wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ibẹ̀ ni àwọn agbésùnmọ̀mí Boko Haram àti ISWAP ti ń gba oúnjẹ àti ohun èlò. Ó fikún un pé kò sí àṣẹ kankan fún ẹnikẹ́ni láti ṣòwò níbẹ̀ láìsí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ológun.

Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tó rí ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti agbègbè Geidam ní ìpínlẹ̀ Yobe sọ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn oníṣòwò ló wà níbẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ òfurufú kọ lù wọ́n ní April 11. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí ọ̀rọ̀ yìí kàn jẹ́ àgbẹ̀ àti oníṣòwò kékeré tí ìṣẹ́ àti ebi fipá mú láti máa ṣòwò níbẹ̀, láìwo ewu tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀.

Agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú òfurufú, Air Vice Marshal Edward Gabkwet, sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé ìkọlù náà dálórí ìsọfúnni tí wọ́n rí pé àwọn agbésùnmọ̀mí ń gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn níbẹ̀.

Tags

Post a Comment

0Comments

Please Select Embedded Mode To show the Comment System.*